Matiu 15:15-20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Peteru wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”
16 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéha ṣe tí ìwọ fi jẹ́ aláìmòye síbẹ̀”? 17 “Ẹyin kò mọ̀ pé ohunkóhun tí ó gba ẹnu wọlé, yóò gba ti ọ̀nà oúnjẹ lọ, a yóò sì yà á jáde? 18 Ṣùgbọ́n ohun tí a ń sọ jáde láti ẹnu, inú ọkàn ni ó ti ń wá, èyí sì ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ 19 Ṣùgbọ́n láti ọkàn ni èrò búburú ti wá, bí ìpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, irọ́ àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. 20 Àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ni ó ń sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ Ṣùgbọ́n láti jẹun láì wẹ ọwọ́, kò lè sọ ènìyàn di ‘aláìmọ́.’ ”
Read full chapter
Marku 4:10
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 (A)Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.