Matiu 17:20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
20 (A)Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”
Read full chapter
Luku 17:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.
Read full chapter
1 Kọrinti 13:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.
Read full chapter
Jakọbu 1:6
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.