Oniwaasu 3:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.
Read full chapter
Oniwaasu 5:18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.
Read full chapter
Oniwaasu 9:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe.
Read full chapter
Isaiah 56:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 “Wá,” ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, “fún mi ní ọtí wáìnì!
Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó
ọ̀la yóò sì dàbí òní,
tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Luku 12:19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’
Read full chapter
1 Kọrinti 15:32
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
32 (A)Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Efesu, àǹfààní kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde,
“Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí á máa mú;
nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.